18. Wọ́n kọ gbogbo oúnjẹwọ́n sì sún mọ́ ẹnu ọ̀nà ikú.
19. Nígbà náà wọn kígbe sí Olúwa nínúìṣòro wọn, ó sì yọ wọ́n nínú ìdàámú wọn
20. Ó rán ọ̀rọ̀ Rẹ̀, ara wọn sí dáó sì yọ̀ wọ́n nínú isà òkú.
21. Ẹ jẹ́ kí wọ́n fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ Rẹ̀ àti iṣẹ ìyanu Rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn.
22. Jẹ́ kí wọn rú ẹbọ ọpẹ́kí wọn kí ó fi ayọ̀ sọ̀rọ̀ iṣẹ́ Rẹ̀.
23. Àwọn ti ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí òkun nínú ọkọ̀ojú omi, wọn jẹ́ oníṣòwò nínú omi ńlá.
24. Wọn ri iṣẹ́ Olúwa,àti iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀ nínú ibú
25. Nítorí tí ó pasẹ, ó sì mú ìjì fẹ́tí ó gbé ríru Rẹ̀ sókè.
26. Wọ́n gòkè lọ sí ọ̀run wọn sìtún sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibú:nítorí ìpọ́njú ọkan wọn di omi
27. Wọ́n ń ta gbọ̀n-ọ́ngbọ̀n-ọ́n bí ọ̀mùtí ènìyàn:ọgbọ́n wọn sì dé òpin.