20. Wọn pa ògo wọn dàsí àwòrán màlúù, tí ń jẹ koríko.
21. Wọ́n gbàgbé Ọlọ́run, ẹni tí í gbàwọ́nẹni tí ó ti ṣe ohun ńlá fún Éjíbítì,
22. Iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Ámùàti ohun ẹ̀rù ni ẹ̀bá òkun pupa
23. Bẹ́ẹ̀ ní, ó sọ wí pé oun yóò pa wọ́n runbí kò ba ṣe tí Mósè, tí ó yàn,tí ó dúró níwájú ẹ̀yà náàtí ó pa ìbínú Rẹ̀ mọ́ láti má pa wọ́n run mọ́
24. Nígbà náà, wọn kẹ́gàn ilẹ̀ dídára náàwọn kò gba ilérí Rẹ̀ gbọ́.
25. Wọn ń kùn nínú àgọ́ wọnwọn kò sì gbọ́ràn sí Olúwa.
26. Bẹ́ẹ̀ ni ó gbé ọwọ́ Rẹ̀ sókè sí wọnkí òun le jẹ́ kí wọn ṣubú nínú ihà,
27. Láti jẹ́ kí àwọn ọmọ Rẹ̀ ṣubú lára orílẹ̀ èdèláti fọ́nu wọn káàkiri lórí ilẹ̀.