Róòmù 9:9-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Nítorí ọ̀rọ̀ ìlérí ni èyí: “Níwọ̀n àmọ́dún ni èmi yóò wá, Sárà yóò sì ní ọmọ ọkùnrin.”

10. Kì sì íṣe kìkì èyí; Ṣùgbọ́n nígbà tí Rèbékà pẹ̀lú lóyún fún ẹnìkan, fún Ísákì baba wa;

11. Nítorí nígbà tí kò tí ì bá àwọn ọmọ náà, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tí ì ṣe rere tàbí búburú, (kí ìpinnu Ọlọ́run nípa ti ìyànfẹ́ kí ó lè dúró, kì í ṣe nípa ti iṣẹ́, bí kòse ti ẹni tí ńpeni;)

12. A ti sọ fún un pé, “Ẹ̀gbọ́n ni yóò máa sin àbúrò.”

Róòmù 9