14. Nítorí pé, iye àwọn tí ẹ̀mí Ọlọ́run bá ń darí ni ọmọ Ọlọ́run.
15. Àti pé, àwa kò ní láti dàbí ẹrú tó ń fi ìbẹ̀rù tẹríba fún ọ̀gá rẹ̀. Ṣùgbọ́n a ní láti hùwà bí ọmọ Ọlọ́run. Ẹni tí a sọdọmọ sí ìdílé, Ọlọ́run tó sì ń pe Ọlọ́run ní “Baba, Baba.”
16. Nítorí ẹ̀mí mímọ́ ń sọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú ọkàn wa, ó sì ń sọ fún wa pé, ní tòótọ́, àwa jẹ́ ọmọ Ọlọ́run.
17. Níwọ̀n ìgbà tí a jẹ́ ọmọ rẹ̀, àwa yóò pín nínú dúkìá rẹ̀. Nítorí nǹkan gbogbo tí Ọlọ́run fún Jésù ọmọ rẹ̀ jẹ́ tiwa pẹ̀lú, ṣùgbọ́n bí á bá ní láti pín ògo rẹ̀, a ní láti setan láti pín nínú ìjìyà rẹ̀.
18. Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀, ìyà tí a ń jẹ nísinsin yìí kò já mọ́ nǹkan nígbà tí a bá fiwé ògo tí yóò fún wa ní ìkẹyìn.
19. Nítorí ẹ̀dá ń dúró ní ìfojúsọ́nà de ìfihàn àwọn ọmọ Ọlọ́run.
20. Nítórí a tẹrí ẹ̀dá ba fún asán, kì í se bí òun ti fẹ́, ṣùgbọ́n nípa ìfẹ́ ẹni tí ó tẹ orí rẹ̀ ba ní ìrètí.
21. Nítorí a ó sọ ẹ̀dá tìkáararẹ̀ di òmìnira kúrò nínú ẹrú ìdibàjẹ́, sí òmìnira ògo àwọn ọmọ Ọlọ́run.
22. Nítorí àwa mọ̀ pé gbogbo ẹ̀dá ni ó jùmọ̀ ń kérora tí ó sì ń rọbí pọ̀ títí di ìsinsin yìí.
23. Kì í se àwọn nìkan, ṣùgbọ́n àwa tìkara wa pẹ̀lú, tí ó nbí àkóso ẹ̀mí, àní àwa tìkara wa ń kérora nínú ara wa, àwa ń dúró de ìṣọdọmọ àní ìdáńdè ara wa.
24. Nítorí ìrètí tí a fi gbà wá là: ṣùgbọ́n ìrètí tí a bá rí kì í se ìrètí nítorí ta ni ń retí ohun tí ó bá rí?
25. Ṣùgbọ́n bí àwa bá ń retí èyí tí àwa kò rí, ǹjẹ́ àwa ń fi sùúrù dúró dè é.