Róòmù 8:11-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Àti pé, bí ẹ̀mí Ọlọ́run, ẹni tí ó jí Jésù kúrò nínú òkú bá ń gbé inú yín, òun yóò mú kí ara yín tí ó kú tún wà láàyè nípa sẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ kan náà tí ń gbé inú yín.

12. Nítorí náà ará, kò jẹ́ ọ̀rọ̀ iyàn fún un yín láti se nǹkan tí ara ẹ̀ṣẹ̀ àtijọ́ ń rọ̀ yín láti se.

13. Nítorí pé bí ẹ̀yin bá ń tẹ̀lé, ẹ̀ṣẹ̀ ti ara ẹ̀yin yóò sọnù, ẹ ó sì sègbé, ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé nípaṣẹ̀ agbára ẹ̀mí mímọ́, ẹ̀yin sẹ́gun ẹ̀mí ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ ibi rẹ̀ nínú yín, ẹ̀yin yóò yè.

14. Nítorí pé, iye àwọn tí ẹ̀mí Ọlọ́run bá ń darí ni ọmọ Ọlọ́run.

15. Àti pé, àwa kò ní láti dàbí ẹrú tó ń fi ìbẹ̀rù tẹríba fún ọ̀gá rẹ̀. Ṣùgbọ́n a ní láti hùwà bí ọmọ Ọlọ́run. Ẹni tí a sọdọmọ sí ìdílé, Ọlọ́run tó sì ń pe Ọlọ́run ní “Baba, Baba.”

16. Nítorí ẹ̀mí mímọ́ ń sọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú ọkàn wa, ó sì ń sọ fún wa pé, ní tòótọ́, àwa jẹ́ ọmọ Ọlọ́run.

17. Níwọ̀n ìgbà tí a jẹ́ ọmọ rẹ̀, àwa yóò pín nínú dúkìá rẹ̀. Nítorí nǹkan gbogbo tí Ọlọ́run fún Jésù ọmọ rẹ̀ jẹ́ tiwa pẹ̀lú, ṣùgbọ́n bí á bá ní láti pín ògo rẹ̀, a ní láti setan láti pín nínú ìjìyà rẹ̀.

18. Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀, ìyà tí a ń jẹ nísinsin yìí kò já mọ́ nǹkan nígbà tí a bá fiwé ògo tí yóò fún wa ní ìkẹyìn.

19. Nítorí ẹ̀dá ń dúró ní ìfojúsọ́nà de ìfihàn àwọn ọmọ Ọlọ́run.

20. Nítórí a tẹrí ẹ̀dá ba fún asán, kì í se bí òun ti fẹ́, ṣùgbọ́n nípa ìfẹ́ ẹni tí ó tẹ orí rẹ̀ ba ní ìrètí.

Róòmù 8