1. Nítorí náà, kò sí ìdálẹ́bi nísinsinyìí fún àwọn tí ó wà nínú Kírísitì.
2. Nítorí nípaṣẹ̀òfin ti ẹ̀mí ìyè nínú Kírísítì Jésù ti sọ mí di òmìnira kúrò lọ́wọ́ òfin ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.
3. Nítorí ohun tí òfin kò lè ṣe, bí ó ti jẹ aláìlera nítorí ara, Ọlọ́run rán ọmọ òun tìkara rẹ̀ ní àwòrán ara ẹ̀ṣẹ̀, ó sì dá ẹ̀ṣẹ̀; àti bi ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀, ó sì dá ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́bi nínú ara,.
4. Kí a lè mú òdodo òfin ṣẹ, nínú wa, nítorí tí àwa ve gẹ́gẹ́ bí ohun ti ara, bí kò ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun ti Ẹ̀mí.
5. Àwọn tí ń ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun ti ara, wọn a máa ronú ohun ti ara; ṣùgbọ́n àwọn ti ń e gẹ́gẹ́ bí ohun ti Ẹ̀mí, wọn a máa ronú ohun ti Ẹ̀mí.
6. Ṣíṣe ìgbọ́ran sí ẹ̀mí Mímọ́ ń yọrí sí ìyè àti àlàáfíà. Ṣùgbọ́n títẹ̀lé ara ẹ̀ṣẹ̀ àtijọ́ náà ń yọrí sí ikú.
7. Nítorí pé ara ẹ̀ṣẹ̀ tí ń gbé inú wa ń tako Ọlọ́run.
8. Ìdí nì yìí tí àwọn tí ó wà lábẹ́ àkóso ara ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n sì ń tẹ̀lé ìfẹ́ ibi wọn, kò le è tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn.
9. Ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ara titun yín ni yóò máa se àkóso yín bí ẹ bá ń rìn nípa ẹ̀mí Ọlọ́run tí ń gbé inú yín (Ẹ rántí pé, bí ẹnìkan kò bá ní ẹ̀mí Kírísítì tí ń gbé inú rẹ̀, irú ẹni bẹ́ẹ̀ kì í se ọmọ-ẹ̀yìn Kirísítì rárá.)