Róòmù 7:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ̀yin kò ha mọ̀, ara: nítorí èmí bá àwọn tí ó mọ òfin sọ̀rọ̀ pé, òfin ní ipá lórí ènìyàn níwọ̀n ìgbà tí ó bá wà láàyè nìkan?

2. Fún àpẹẹrẹ, nípa òfin ní a de obìnrin mọ́ ọkọ rẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ọkọ náà wà láàyè, ṣùgbọ́n bí ọkọ rẹ̀ bá kú, a tú u sílẹ̀ kúrò nínú òfin ìgbéyàwó náà.

3. Nígbà náà, bí ó bá fẹ́ ọkùnrin mìíràn nígbà tí ọkọ rẹ̀ wà láàyé, panṣagà ní a ó pè é. Ṣùgbọ́n bí ọkọ rẹ̀ bá kú, ó bọ́ lọ́wọ́ òfin náà, kí yóòsì jẹ́ panṣagà, kódà bí ó bá ní ọkọ mìíràn.

4. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ará mi, ẹ̀yin pẹ̀lú ti di òkú sí òfin nípa ara Kírísítì, kí ẹ̀yin kí ó lè ní ẹlòmìíràn, àní ẹni náà tí a jí dìde kúrò nínú òkú, kí àwa kí ó lè so èso fún Ọlọ́run

5. Nítorí ìgbà tí ìfẹ́kúfẹ́ ara ń darí wa, ar ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà nípa òfin, ó ń ṣisẹ́ nínú àwọn ara wa láti so èso fún ikú.

6. Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí, nípa kíkú láti ipasẹ̀ ohun tó so wápọ̀ tẹ́lẹ̀ rí, a ti tú wa sílẹ̀ kúrò nínú òfin, kí a lè sin ín ní ìlànà tuntun ti Ẹ̀mí, kì í se ní ìlànà ti àtijọ́ tí òfin gùnlé.

Róòmù 7