Róòmù 6:16-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Àbí ẹ̀yin kò mọ̀ pé, ẹnikẹ́ni lè yan ọ̀gá tí ó bá fẹ́? Ẹ lè yan ẹ̀ṣẹ̀ (pẹ̀lú ikú) tàbí ìgbọ́ràn (pẹ̀lú ìdáláre). Ẹnikẹ́ni tí ẹ bá yọ̀ǹda ara yín fún, òun náà ni yóò jẹ́ ọ̀gá yín, ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ẹrú rẹ̀.

17. Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yin ti se ìgbọ́ràn, pẹ̀lú ọkàn yín, sí ẹ̀kọ́ èyí tí Ọlọ́run fi lé yín lọ́wọ́.

18. Nísinsìnyìí, ẹ ti dòminira kúrò lọ́wọ́ ọ̀gá yín àtijọ́, èyí tíí ṣe ẹ̀ṣẹ̀, ẹ sì ti di ẹrú ọ̀gá tuntun èyí ni òdodo.

19. Èmi ń sọ̀rọ̀ lọ́nà báyìí, ní lílo àpèjúwe àwọn ẹrú àti àwọn ọ̀gá nítorí kí ó ba le yé yín. Gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fi ìgbà kan jẹ́ ẹrú sí oríṣiríṣi ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹ ní láti di ẹrú gbogbo èyí tíi ṣe rere tí ó sì jẹ́ Mímọ́.

20. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì nígbà tí ẹ̀yin jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin kò ṣe wàhálà púpọ̀ pẹ̀lú òdodo.

21. Àti pé, kí ni ìyọrísí rẹ̀? Dájúdájú àbájáde rẹ̀ kò dára. Níwọ̀n ìgbà tí ojú ń tì ọ́ nísinsìnyìí láti ronu nípa àwọn wọ̀n-ọn-nì tí o ti máa ń sọ nítorí gbogbo wọn yọrí sí ìparun ayérayé.

22. Ṣùgbọ́n báyìí, ẹ ti bọ́ kúrò lọ́wọ́ agbára ẹ̀ṣẹ̀, ẹ sì ti di ìránṣẹ́ Ọlọ́run àwọn ìbùkún rẹ̀ sí yin ni ìwà mímọ́ àti ìyè tí kò nípẹ̀kun.

Róòmù 6