Róòmù 4:22-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Nítorí náà ni a sì ṣe kà á sí òdodo fún un.

23. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà, “A kà á sí òdodo fún un,” ni a kọ kì í ṣe kìkì nítorí tirẹ̀ nìkan.

24. Ṣùgbọ́n nítorí tiwa pẹ̀lú. A ó sì kà á sí fún wa, bí àwa bá gba ẹni tí ó gbé Jésù Olúwa wa dìde kúrò nínú òkú gbọ́.

25. Ẹni tí a pa fún ẹ̀ṣẹ̀ wa, tí a sì jí dìde nítorí ìdáláre wa.

Róòmù 4