Róòmù 16:12-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ẹ kí Tírífẹ́nà àti Tírífósà, àwọn obìrin tí wọ́n se iṣẹ́ takuntakun nínú Olúwa.Ẹ kí Pásísì ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, obìnrin mìíràn tí ó se iṣẹ́ takuntakun nínú Olúwa.

13. Ẹ kí Rúfọ́ọ̀sì, ẹni tí a yàn nínú Olúwa, àti ìyá rẹ̀ àti ẹni tí ó ti jẹ́ ìyá fún èmi náà pẹ̀pú.

14. Ẹ kí Ásínkírítúsì, Fílégónì, Hérímésì, Pátíróbà, Hérímásì àti àwọn arákùnrin tí ó wà pẹ̀lú wọn.

15. Ẹ kí Fílólóhù, àti Júlíà, Néréù, àti arábìnrin rẹ̀, àti Ólíḿpà, àti gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó wà pẹ̀lú wọn.

Róòmù 16