1. Nítorí náà mo fi ìyọ́nú Ọlọ́run bẹ̀ yín ará, kí ẹ̀yin kí ó fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè mímọ́, ìtẹ́wọ́gbà, èyí ni iṣẹ́-ìsìn yín tí ó tọ̀nà.
2. Kí ẹ má sì da ara yín pọ̀ mọ́ ayé yìí; ṣùgbọ́n kí ẹ paradà láti di titun ní ìrò-inú yín, kí ẹ̀yin kí ó lè rí ìdí ìfẹ́ Ọlọ́run, tí ó dára, tí ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà, ti ó sì pé.
3. Ǹjẹ́ mo wí fún olúkúlùkù ènìyàn tí ó wà nínú yín, nípa oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún mi, kí ó má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ; ṣùgbọ́n kí ó le rò níwọ̀ntún-wọ̀nsì, bí Ọlọ́run ti fi ìwọ̀n ìgbàgbọ́ fún olukúkùlù.
4. Nítorí gẹ́gẹ́ bí àwa ti ní ẹ̀yà pípọ̀ nínú ara kan, tí gbogbo ẹ̀yà kò sì ní iṣẹ́ kan náà:
5. Bẹ́ẹ̀ ni àwa, tí a jẹ́ pípọ̀, a jẹ́ ara kan nínú Kírísítì, àti olukúlùkú ẹ̀yà ara ọmọnìkejì rẹ̀.