10. Nítorí pé, nípa ìgbàgbọ́ nínú ọkàn ni ènìyàn le gbà ní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ ni ẹnu ni a sì fi ń sọ fún àwọn ẹlòmíràn ní ti ìgbàgbọ́ wa. Nípa bẹ́ẹ̀, a sì sọ ìgbàlà wa di ohun tí ó dájú.
11. Nítorí pé, ìwé Mímọ́ sọ pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba Kírísítì gbọ́ kò ní kábámọ̀; ojú kò ní ti olúwa rẹ̀ láéláé.”
12. Òtítọ́ ni èyí pé, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́, ìbáà ṣe Júù tàbí aláìkọlà; Ọlọ́run kan ni ó wà fún gbogbo wa, ó sì ń pín ọ̀rọ̀ rẹ̀ láì ní ìwọ̀n fún ẹnikẹ́ni tí ó bá bèèrè rẹ̀.
13. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sà à ti pe orúkọ Olúwa ni a ó gbàlà.”
14. Ṣùgbọ́n báwo ni wọ́n ṣe le ké pé ẹni tí wọn kò gbàgbọ́? Wọn ó ha sì ti ṣe gba ẹni tí wọn kò gbúró rẹ̀ rí gbọ́? Wọn o há sì ti ṣe gbọ́ láì sí oníwàásù?
15. Wọ́n ó ha sì ti ṣe wàásù, bí kò ṣe pé a rán wọn? Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹsẹ̀ àwọn tí ń wàásù ìyìn rere àlàáfíà ti dára tó, àwọn tí ń wàásù ìhìn ìyìn àyọ̀ ohun rere!”
16. Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo wọn ni ó gbọ́ ti ìyìn rere. Nítorí Ìsáià wí pé, “Olúwa, tali ó gba ìyìn wa gbọ́?”