Róòmù 1:3-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Nípa ìfiyèsí ọmọ rẹ̀, ẹni tí ó jẹ́ ìran Dáfídì nípa ìbí ti ènìyàn.

4. Ẹni tí a pinnu rẹ̀ láti jẹ́ ọmọ Ọlọ́run nínú agbára gẹ́gẹ́ bí Ẹmi ìwà mímọ́, nípa àjíǹde kúrò nínú òkú, àní Jésù Kírísítì Olúwa wa.

5. Láti ọdọ ẹni tí àwa rí oore-ọ̀fẹ́ àti jíjẹ́ Àpósítélì gbà, láti wàásù fún gbogbo ènìyàn orílẹ̀-èdè kí wọn kí ó lè wá sínú ìgbàgbọ́ èyíni ní orúkọ rẹ̀.

6. Ẹ̀yin pẹ̀lú si wa lára àwọn tí a pè sọ́dọ̀ Jésù Kírísítì.

7. Sí gbogbo àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run tí ó wà ní Róòmù tí a ti pè láti jẹ́ ènìyàn mímọ́:Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa Jésù Kírísítì.

8. Ní àkọ́kọ́, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nípaṣẹ̀ Jésù kírísítì fún gbogbo yín, nítorí a ń ròyìn ìgbàgbọ́ yin káàkiri gbogbo ayé.

9. Ọlọ́run, ẹni tí èmí ń sìn tí mo sì fi gbogbo ọkàn mi jìn fún un láti máa wàásù ìyìnrere ọmọ rẹ̀, bí ó ti ṣe pé ní àìsinmi ni èmí ń rántí yín nígbà gbogbo nínú àdúrà mi

10. nínú àdúrà mi ìgbà gbogbo; mo tún ń gbàdúrà wí pé nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run kí ọ̀nà ó sí fún mi láti wá sọ́dọ̀ yín.

11. Nítorí èmi ń fẹ́ gidigidi láti tọ̀ yín wá, kí èmi lè fún yín ní ẹ̀bùn ẹ̀mí díẹ̀, kí a bá a le sọ yín di alágbára nínú Olúwa,

12. èyí nì ni pé, kí a lè jẹ́ ìwúrí fún ara wa nípa ìgbàgbọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan wa.

13. Mo fẹ́ kí ẹ mọ èyí, ẹ̀yin ará mi, pé mo ti gbìyànjú lọ́pọ̀ ìgbà láti tọ̀ yín wá, (ṣùgbọ́n ìdíwọ́ wà fún mi), kí èmi ki ó lè jèrè ọkàn díẹ̀ láàrin yín, gẹ́gẹ́ bí mo ti ní in láàrin àwọn aláìkọlà yóòkù.

14. Nítorí mo jẹ́ ajigbèsè sí Gíríkì àti sí àwọn ẹlòmíràn tí kì í se Gíríkì, sí àwọn ọlọ́gbọ́n àti sí àwọn aláìgbọ́n.

Róòmù 1