13. Mo fẹ́ kí ẹ mọ èyí, ẹ̀yin ará mi, pé mo ti gbìyànjú lọ́pọ̀ ìgbà láti tọ̀ yín wá, (ṣùgbọ́n ìdíwọ́ wà fún mi), kí èmi ki ó lè jèrè ọkàn díẹ̀ láàrin yín, gẹ́gẹ́ bí mo ti ní in láàrin àwọn aláìkọlà yóòkù.
14. Nítorí mo jẹ́ ajigbèsè sí Gíríkì àti sí àwọn ẹlòmíràn tí kì í se Gíríkì, sí àwọn ọlọ́gbọ́n àti sí àwọn aláìgbọ́n.
15. Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń làkàkà láti wá sí Róòmù àti láti fi gbogbo agbára mi wàásù ìyìn rere Ọlọ́run sí i yín.
16. Èmi kò tijú ìyìn rere Jésù, nítorí agbára Ọlọ́run ní ín ṣe láti gba gbogbo àwọn tí ó bá gbàgbọ́ là, ọ̀rọ̀ yìí ni a kọ́kọ́ wàásù sí àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nísinsin yìí fún aláìkọlà pẹ̀lú.
17. Nítorí nínú ìyìnrere ni òdodo Ọlọ́rùn ti farahàn, òdodo Ọlọ́run láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé Mímọ́ pé, “Olódodo yóò yè nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀.”
18. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìbínú rẹ̀ hàn láti ọ̀run wá sí gbogbo àìwà-bí-Ọlọ́run àti gbogbo àìṣòdodo ènìyàn, àwọn tí ń fi ìwà búburú dènà ìmọ̀ òtítọ́ lọ́dọ̀ ènìyàn.