Òwe 5:11-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ní ìgbẹ̀yìn ayé rẹ ìwọ yóò kérora,nígbà tí agbára rẹ àti ara rẹ bá ti joro tán

12. Ìwọ yóò wí pé, “Mo ti kórìíra ẹ̀kọ́ tó!Ọkàn mi ṣe wá kóòríra ìbáwí!

13. N kò gbọ́ràn sí àwọn olùkọ́ mi lẹ́nu,tàbí kí n fetí sí àwọn tí ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́.

14. Mo ti bẹ̀rẹ̀ ìparun pátapátaní àárin gbogbo àwùjọ ènìyàn.”

15. Mu omi láti inú un kànga tìrẹOmi tí ń ṣàn láti inú kànga rẹ.

Òwe 5