3. Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ àti òtítọ́ ṣíṣe fi ọ́ sílẹ̀ láéláéso wọ́n mọ́ ọrùn rẹ,kọ wọ́n sí síléètì àyà rẹ.
4. Nígbà náà ni ìwọ yóò rí ojú rere àti orúkọ rerení ojú Ọlọ́run àti lójú ènìyàn.
5. Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹmá ṣe sinmi lé òye ara à rẹ;
6. Jẹ́wọ́ rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹyóò sì ṣe àkóso ọ̀nà rẹ.
7. Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara à rẹbẹ̀rù Olúwa kí o sì kórìíra ibi.
8. Èyí yóò mú ìlera fún ara à rẹàti okun fún àwọn egungun rẹ.
9. Fi ọrọ̀ rẹ bọ̀wọ̀ fún Olúwa,pẹ̀lú àkọ́so oko ò rẹ
10. Nígbà náà ni àká rẹ yóò kún àkúnyaàgbá rẹ yóò kún à kún wọ́ sílẹ̀ fún wáìnì tuntun.