10. Nígbà náà ni àká rẹ yóò kún àkúnyaàgbá rẹ yóò kún à kún wọ́ sílẹ̀ fún wáìnì tuntun.
11. Ọmọ mi, má ṣe kẹ́gàn ìbáwí Olúwamá si ṣe bínú nígbà tí ó bá ń bá ọ wí,
12. Nítorí Olúwa a máa bá àwọn tí ó fẹ́ràn wíbí baba ti í bá ọmọ tí ó bá nínú dídùn sí wí.
13. Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ní ìmọ̀,ẹni tí ó tún ní òye síi