Òwe 27:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Má ṣe yangàn nítorí ọ̀lanítorí o kò mọ ohun tí ọjọ́ kan le è mú wáyé.

2. Jẹ́ kí ẹlòmíràn yìn ọ́ dípò ẹnu ara rẹàní ẹlòmíràn, kì í ṣe ètè ìwọ fúnra rẹ.

3. Òkúta wúwo, erùpẹ̀ sì wúwoṣùgbọ́n ìmúbínú un aṣiwèrè wúwo ju méjèèjì lọ.

4. Ìbínú ni ìkà, ìrunú sì burú púpọ̀ṣùgbọ́n tani ó le è dúró níwájú owú?

5. Ìbániwí gbangba sànju ìfẹ́ ìkọ̀kọ̀ lọ.

Òwe 27