17. Má ṣe yọ̀ nígbà tí ọ̀tá rẹ bá ṣubú;nígbà tí ó bá kọsẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yọ̀
18. àìṣe bẹ́ẹ̀ Olúwa yóò rí i yóò sì bínúyóò sì yí ìbínú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.
19. Má ṣe fòyà nítorí àwọn ènìyàn ibitàbí jowú àwọn ènìyàn búburú,
20. nítorí ẹni ibi kò ní ìrètí ọjọ́ iwájúa ó sì pa fìtílà àwọn ènìyàn búburú kú.
21. Bẹ̀rù Olúwa àti ọba, ọmọ mi,má sì ṣe dara pọ̀ pẹ̀lú àwọn olórí kunkun
22. nítorí àwọn méjèèjì yóò rán ìparun òjijì sórí wọn,ta ni ó sì mọ irú ìyọnu tí wọ́n lè mú wá?
23. Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú tún jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́gbọ́nláti ṣe ojúṣàájú níbi ìdájọ́ kò dára rárá:
24. Ẹnikẹ́ni tí ó wí fún ẹlẹ́bi pé, “Ìwọ lo jàre”àwọn ènìyàn yóò ṣẹ́ èpè fún un àwọn orílẹ̀ èdè yóò sì kọ̀ ọ́.
25. Ṣùgbọ́n yóò dára fún àwọn tí ń dá ẹlẹ́bi lẹ́bi,ọ̀pọ̀ ìbùkún yóò sì wá sórí wọn.
26. Ìdáhùn òtítọ́ó dàbí ìfẹnu-koni-ní-ẹnu.
27. Parí gbogbo iṣẹ́ ajé rẹsì rí i pé oko rẹ ti ṣe dáradára;lẹ́yìn náà kọ́ ilé rẹ.
28. Má ṣe rojọ́ èké mọ́ aládúgbò rẹ láìnídìí,tàbí kí o fi ètè rẹ tannijẹ.