Òwe 23:9-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Má ṣe sọ̀rọ̀ ní etí aṣiwèrè (òmùgọ̀);nítorí tí yóò gan ọgbọ́n ọ̀rọ̀ rẹ.

10. Má ṣe sí ààlà àtijọ́ kúrò;má sì ṣe bọ́ sínú oko aláìní baba.

11. Nítorí pé Olùràpadà wọn lágbára;yóò gba ìjà wọn jà sí ọ.

12. Fi àyà sí ẹ̀kọ́,àti etí rẹ sí ọ̀rọ̀ ìmọ̀.

Òwe 23