Òwe 23:5-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ìwọ ó ha fi ojú rẹ lépa ohun tí kò sí?Nítorí tí ọ̀rọ̀ hu ìyẹ́-apá fún ara rẹ̀,ó sì ń fò bí idì ní ojú ọ̀run.

6. Má ṣe jẹ oúnjẹ olójú búburú,bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe fẹ́ oúnjẹ-dídùn rẹ̀.

7. Nítorí pé bí ẹni tí ń sírò ní ọkàn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó rí:“Má a jẹ, kí o sì máa mu,” ni ó ń wí fún ọ;ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ kò pẹ̀lú rẹ.

8. Òkèlè tí ìwọ jẹ ni ìwọ ó pọ̀ jáde,ìwọ a sì sọ ọ̀rọ̀ dídùn rẹ̀ nù.

9. Má ṣe sọ̀rọ̀ ní etí aṣiwèrè (òmùgọ̀);nítorí tí yóò gan ọgbọ́n ọ̀rọ̀ rẹ.

10. Má ṣe sí ààlà àtijọ́ kúrò;má sì ṣe bọ́ sínú oko aláìní baba.

11. Nítorí pé Olùràpadà wọn lágbára;yóò gba ìjà wọn jà sí ọ.

Òwe 23