Òwe 23:31-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

31. Ìwọ má ṣe wò ọtí-wáìnì nígbà tí ó pọ́n,nígbà tí ó bá ń fi àwọ̀ rẹ̀ hàn nínú ago,tí a gbé e mì, tí ó ń dùn.

32. Níkẹyìn òun á bunisán bí ejò,a sì bunijẹ bí i paramọ́lẹ̀.

33. Ojú rẹ yóò wò àwọn àjèjì obìnrin,àyà rẹ yóò sì sọ̀rọ àyídáyidà.

34. Nítòótọ́, ìwọ ó dàbí ẹni tí ó dùbúlẹ̀ ní àárin òkun,tàbí ẹni tí ó dúbúlẹ̀ lókè-ọkọ̀.

35. Ìwọ ó sì wí pé, “Wọ́n lù mí; kò dùn mí;wọ́n lù mí, èmi kò sì mọ̀:nígbàwo ni èmi ó jí?Èmi ó tún máa wá òmíràn láti mu.”

Òwe 23