Òwe 20:9-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Táni ó le è wí pé, “Mo ti ṣe ọkàn mi ní mímọ́,mo mọ́, n kò sì lẹ́ṣẹ̀”?

10. Ìdíwọ̀n èké àti òṣùwọ̀n ìrẹ́jẹ Olúwa kórìíra méjèèjì.

11. Kódà a mọ ọmọdé nípa iṣẹ́ rẹ̀nípa pe bóyá iṣẹ́ rẹ mọ́ tàbí pé ó tọ̀nà.

12. Etí tí ó ń gbọ́ àti ojú tí ó ń ríran Olúwa ni ó dá méjèèjì.

Òwe 20