Òwe 20:25-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Ìdẹkùn ni fún ènìyàn láti ṣe ìlérí kíákíánígbà tí ó bá sì yá kí ó máa ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wò.

26. Ọlọgbọ́n ọba tú ènìyàn búburú ká;Ó sì fi òòlọ ìpakà lọ̀ wọ́n.

27. Àtùpà Olúwa ń ṣe àwárí ẹ̀mí ènìyàna máa ṣàwárí ibi ìkọ̀kọ̀ inú

28. Ìfẹ́ àti òdodo pa ọba mọ́,nípa ìfẹ́, ìtẹ́ rẹ̀ wà láìléwu.

Òwe 20