Òwe 19:18-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Bá ọmọ rẹ wí nítorí nínú ìyẹn ni ìrètí wà;àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ lọ́wọ́ nínú iparun un rẹ̀.

19. Ènìyàn onínú-fùfù gbọdọ̀ gba èrè ìwà rẹ̀bí ìwọ bá gbàá là, ìwọ yóò tún ní láti ṣe é lẹ́ẹ̀kan síi.

20. Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ẹ̀kọ́ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín ìwọ yóò di ọlọ́gbọ́n.

21. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ète inú ọkàn ènìyànṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa ní ó máa ń borí.

Òwe 19