Òwe 14:4-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Níbi tí kò sí ẹran, ibùjẹ ẹran a máa mọ́ tónítóníṣùgbọ́n, nípa agbára akọ màlúù ni ọ̀pọ̀ ìkórè ti ń wá.

5. Ẹlẹ́rìí tí ń sòótọ́ kì í tan niṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké a máa tú irọ́ jáde.

6. Ẹlẹ́gàn ń wá ọgbọ́n kò sì rí rárá,ṣùgbọ́n ìmọ̀ máa ń wà fún olóye.

7. Má ṣe súnmọ́ aláìgbọ́n ènìyàn,nítorí ìwọ kì yóò rí ìmọ̀ ní ètè rẹ̀.

Òwe 14