Òwe 14:24-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Ọrọ̀ Ọlọgbọ́n ènìyàn ni adé orí wọnṣùgbọ́n ìwà aláìgbọ́n ń mú ìwà òmùgọ̀ wá.

25. Ẹlẹ́rìí tí ó ṣòótọ́ gba ẹ̀mí làṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké jẹ́ ẹlẹ́tàn.

26. Ẹni tí ó bẹ̀rù Olúwa ni ilé ìṣọ́ ààbòyóò sì tún jẹ́ ààbò fún àwọn ọmọ rẹ̀.

27. Ìbẹ̀rù Olúwa jẹ́ oríṣun ìyè,tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìkẹ́kùn ikú.

28. Ènìyàn púpọ̀ ní ìlú jẹ́ ògo Ọba,ṣùgbọ́n láì sí ìjòyè, Ọba á parun.

29. Onísùúrù ènìyàn ní òye tí ó pọ̀,ṣùgbọ́n onínú fùfù ènìyàn máa ń fi ìwà aṣiwèrè hàn.

Òwe 14