Òwe 14:10-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ọkàn kọ̀ọ̀kan ló mọ ẹ̀dùn ọkàn tirẹ̀kò sì sí ẹnìkan tó le è bá ọkàn mìíràn pín ayọ̀ rẹ̀.

11. A ó pa ilé ènìyàn búburú runṢùgbọ́n àgọ́ Olódodo yóò máa gbèrú síi.

12. Ọ̀nà kan wà tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyàn,ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín, a máa já sí ikú.

13. Kódà nígbà tí a ń rẹ́rìnín, ọkàn leè máa kérora;ayọ̀ sì leè yọrí sí ìbànújẹ́.

14. A ó san án lẹ́kùnrẹ́rẹ́ fún aláìgbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀Ènìyàn rere yóò sì gba èrè fún tirẹ̀.

Òwe 14