Òwe 13:9-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ìmọ́lẹ̀ olódodo tàn roro,ṣùgbọ́n àtùpà ènìyàn búburú ni a pa kú.

10. Ìgbéraga máa ń dá ìjà sílẹ̀ niṣùgbọ́n ọgbọ́n wà nínú àwọn tí ń gba ìmọ̀ràn.

11. Owó tí a fi ọ̀nà èrú kó jọ yóò sí lọ,ṣùgbọ́n ẹni tí ń kó owó jọ díẹ̀ díẹ̀ yóò pọ̀ síi.

Òwe 13