Òwe 12:4-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Aya oníwà rere ni adé ọkọ rẹ̀ṣùgbọ́n aya adójútini dàbí ìgbà tí inú egungun rẹ̀ jẹrà.

5. Ète àwọn Olódodo dáraṣùgbọ́n ìmúra ènìyàn búburú jẹ́ ẹ̀tàn.

6. Ọ̀rọ̀ ènìyàn búburú lúgọ de ẹ̀jẹ̀ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ àwọn Olódodo gbà wọ́n là.

7. A sí àwọn ènìyàn búburú ní ìdí, wọn kò sì sí mọ́;ṣùgbọ́n ilé Olódodo dúró ṣinṣin.

8. A ń yín ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ọgbọ́n rẹ̀ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ọlọ́pọlọ wúruwùru ni a kẹ́gàn.

9. Ó sàn kí a má jẹ́ ènìyàn pàtàkì kí a sì ní ìránṣẹ́ju kí a díbọ́n pé a jẹ́ ẹni pàtàkì láì lóúnjẹ.

10. Ènìyàn rere ń ṣaájò ohun tí àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ nílòÀmọ́ ìwà tó dára jù tí ènìyàn búburú lè hù, ibi ni.

11. Ẹni tí ó bá dáko yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ,ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa òjìji lásánlàsàn kò gbọ́n.

12. Ènìyàn búburú ń fẹ́ ìkógún àwọn ènìyàn ìkàṣùgbọ́n gbòǹgbò Olódodo ń gbilẹ̀.

13. A mú ènìyàn búburú nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹsẹ̀ rẹ̀ṣùgbọ́n Olódodo bọ́ kúrò lọ́wọ́ ìdàámú.

Òwe 12