Òwe 1:12-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Jẹ́ ká gbé wọn mì láàyè, bí ibojì òkú,àti lódindi, bí àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sínú kòtò;

13. A ó rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tó níye lóría ó sì fi ìkógún kún inú ilé wa;

14. Dara pọ̀ mọ́ wa,a ó sì jọ powó sínú àpò kan náà”

15. Ọmọ mi, má ṣe bá wọn lọ,má ṣe rìn ní ojú ọ̀nà wọn;

16. Nítorí ẹsẹ̀ wọn ń sáré sí ẹ̀ṣẹ̀,wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.

17. Wàhálà asán ni kí ènìyàn máa dẹ okùn de ẹyẹ,ní ìṣojú u gbó ẹyẹ!

Òwe 1