Orin Sólómónì 8:12-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ṣùgbọ́n ọgbà àjàrà mi jẹ́ tèmi, ó wà fún mi;ẹgbẹ̀rún ṣékélì jẹ́ tìrẹ, ìwọ Sólómónì,igba sì jẹ́ ti àwọn alágbàtọ́jú èso.

13. Ìwọ tí ń gbé inú ọgbà,àwọn ọ̀rẹ́ rẹ dẹtí sí ohùn rẹ,Jẹ́ kí èmi náà gbọ́ ohùn rẹ!

14. Yára wá, Olùfẹ́ mi,kí ìwọ kí ó sì rí bí abo egbin,tàbí gẹ́gẹ́ bí ọmọ àgbọ̀nrín,lórí òkè òórùn dídùn.

Orin Sólómónì 8