Orin Sólómónì 3:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Àwọn ọdẹ tí ń ṣọ́ ìlú rí miBí wọ́n ṣe ń rìn yíká ìlú.“Ǹjẹ́ ìwọ ti rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́?”

4. Gẹ́rẹ́ tí mo fi wọ́n sílẹ̀Ni mo rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́.Mo dì í mú, èmi kò sì jẹ́ kí ó lọtítí tí mo fi mú u wá sílé ìyá mi,sínú yàrá ẹni tí ó lóyún mi

5. Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù,Mo fi àwọn abo egbin àti abo àgbọ̀nrín igbó fi yín búkí ẹ má ṣe rú olùfẹ́ mi sókèkí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú

6. Ta ni ẹni tí ń ti ijù jáde wábí ìkuku èéfíntí a ti fi òjíá àti tùràrí kùn lárapẹ̀lú gbogbo ètù olóòórùn oníṣòwò?

Orin Sólómónì 3