Orin Sólómónì 1:9-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Olùfẹ́ mi,Mo fi ọ́ wé ẹṣin mi nínú kẹ̀kẹ́ Fáráò.

10. Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dára ní ohun ọ̀ṣọ́,Ọrùn rẹ sì yẹ ọ̀ṣọ́ ìlẹ̀kẹ̀

11. A ó fi wúrà ṣe òrùka etí fún ọ,A ó fi fàdákà ṣe ìlẹ̀kẹ̀.

12. Nígbà tí ọba wà ní orí ìjókòó rẹ̀.Òróró ìkunra mi tú òórùn jáde.

Orin Sólómónì 1