Oníwàásù 8:8-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Kò sí ẹni tí ó lágbára lórí afẹ́fẹ́ láti gbàá dúrónítorí náà, kò sí ẹni tí ó ní agbára lórí ọjọ́ ikú rẹ̀.Bí ó ti jẹ́ wí pé kò sí ẹni tí a dá sílẹ̀ nígbà ogun,bẹ́ẹ̀ náà ni ìkà kò ní fi àwọn tí ó ń ṣe é sílẹ̀;bí ó ti jẹ́ wí pé kò sí ẹni tí a dá sílẹ̀ nígbà ogun,bẹ́ẹ̀ náà ni ìfà kò ní fi àwọn tí ó ń ṣe é sílẹ̀.

9. Gbogbo ǹnkan wọ̀nyí ni mo ti rí, tí mo sì ń mú lò ní ọkàn mi sí gbogbo iṣẹ́ tí a ti ṣe lábẹ́ oòrùn. Ìgbà kán wà tí ẹnìkan ń ṣe olórí àwọn tó kù fún ìpalára rẹ̀.

10. Nígbà náà ni mo tún rí ìsìnkú òsìkà—àwọn tí wọ́n máa ń wá tí wọ́n sì ń lọ láti ibi mímọ́ kí wọn sì gba ìyìn ní ìlú tàbí tí wọ́n ti ṣe èyí. Eléyìí pẹ̀lú kò ní ìtumọ̀.

11. Nígbà tí a kò bá tètè ṣe ìdájọ́ fún ẹlẹ́ṣẹ̀ kíákíá, ọkàn àwọn ènìyàn a máa kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìmọ̀ láti ṣe ibi.

12. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òsìkà ènìyàn ń ṣe ọgọ́rùn-ún ibi ṣíbẹ̀ tí ó sì wà láàyè fún ìgbà pípẹ́, mo mọ̀ wí pé yóò dára fún ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run.

Oníwàásù 8