Oníwàásù 8:2-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Mo sọ wí pé, pa òfin ọba mọ́, nítorí pé, ìwọ ti ṣe ìbúra níwájú Ọlọ́run.

3. Má ṣe jẹ́ kí ojú kán ọ láti kúrò ní iwájú ọba, má ṣe dúró ní ohun búburú, nítorí yóò ṣe ohunkóhun tí ó bá tẹ́ ẹ lọ́rùn.

4. Níwọ̀n ìgbà tí ọ̀rọ̀ ọba ni àṣẹ, ta ni ó le è ṣọ fún-un wí pé, “Kí ni ìwọ ń ṣe?”

5. Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa àṣẹ rẹ̀ mọ́, kò ní wá sí ìpalára kankan,àyà ọlọgbọ́n ènìyàn yóò sì mọ àsìkò tí ó tọ́ àti ọ̀nà tí yóò gbà ṣe é.

6. Ohun gbogbo ni ó ní àsìkò àti ọ̀nà tí ó tọ́ láti ṣe,ṣùgbọ́n, òsì ènìyàn pọ̀ sí orí ara rẹ̀.

7. Níwọ̀n ìgbà tí kò sí ẹni tí ó mọ ọjọ́-ọ̀lá,tani ó le è sọ fún-un ohun tí ó ń bọ̀?

8. Kò sí ẹni tí ó lágbára lórí afẹ́fẹ́ láti gbàá dúrónítorí náà, kò sí ẹni tí ó ní agbára lórí ọjọ́ ikú rẹ̀.Bí ó ti jẹ́ wí pé kò sí ẹni tí a dá sílẹ̀ nígbà ogun,bẹ́ẹ̀ náà ni ìkà kò ní fi àwọn tí ó ń ṣe é sílẹ̀;bí ó ti jẹ́ wí pé kò sí ẹni tí a dá sílẹ̀ nígbà ogun,bẹ́ẹ̀ náà ni ìfà kò ní fi àwọn tí ó ń ṣe é sílẹ̀.

9. Gbogbo ǹnkan wọ̀nyí ni mo ti rí, tí mo sì ń mú lò ní ọkàn mi sí gbogbo iṣẹ́ tí a ti ṣe lábẹ́ oòrùn. Ìgbà kán wà tí ẹnìkan ń ṣe olórí àwọn tó kù fún ìpalára rẹ̀.

Oníwàásù 8