Oníwàásù 8:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ta ni ó dàbí ọlọgbọ́n ènìyàn?Ta ni ó mọ ìtumọ̀ ohun gbogbo?Ọgbọ́n a máa mú ojú ènìyàn dánó sì máa ń pààrọ̀ ìrínisí rẹ̀.

2. Mo sọ wí pé, pa òfin ọba mọ́, nítorí pé, ìwọ ti ṣe ìbúra níwájú Ọlọ́run.

3. Má ṣe jẹ́ kí ojú kán ọ láti kúrò ní iwájú ọba, má ṣe dúró ní ohun búburú, nítorí yóò ṣe ohunkóhun tí ó bá tẹ́ ẹ lọ́rùn.

4. Níwọ̀n ìgbà tí ọ̀rọ̀ ọba ni àṣẹ, ta ni ó le è ṣọ fún-un wí pé, “Kí ni ìwọ ń ṣe?”

5. Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa àṣẹ rẹ̀ mọ́, kò ní wá sí ìpalára kankan,àyà ọlọgbọ́n ènìyàn yóò sì mọ àsìkò tí ó tọ́ àti ọ̀nà tí yóò gbà ṣe é.

6. Ohun gbogbo ni ó ní àsìkò àti ọ̀nà tí ó tọ́ láti ṣe,ṣùgbọ́n, òsì ènìyàn pọ̀ sí orí ara rẹ̀.

7. Níwọ̀n ìgbà tí kò sí ẹni tí ó mọ ọjọ́-ọ̀lá,tani ó le è sọ fún-un ohun tí ó ń bọ̀?

8. Kò sí ẹni tí ó lágbára lórí afẹ́fẹ́ láti gbàá dúrónítorí náà, kò sí ẹni tí ó ní agbára lórí ọjọ́ ikú rẹ̀.Bí ó ti jẹ́ wí pé kò sí ẹni tí a dá sílẹ̀ nígbà ogun,bẹ́ẹ̀ náà ni ìkà kò ní fi àwọn tí ó ń ṣe é sílẹ̀;bí ó ti jẹ́ wí pé kò sí ẹni tí a dá sílẹ̀ nígbà ogun,bẹ́ẹ̀ náà ni ìfà kò ní fi àwọn tí ó ń ṣe é sílẹ̀.

9. Gbogbo ǹnkan wọ̀nyí ni mo ti rí, tí mo sì ń mú lò ní ọkàn mi sí gbogbo iṣẹ́ tí a ti ṣe lábẹ́ oòrùn. Ìgbà kán wà tí ẹnìkan ń ṣe olórí àwọn tó kù fún ìpalára rẹ̀.

Oníwàásù 8