24. Ohun tí ó wù kí ọgbọ́n le è jẹ́,ó ti lọ jìnnà, ó sì jinlẹ̀ta ni ó le è ṣe àwárí rẹ̀?
25. Mó wá ròó nínú ọkàn mi láti mọ̀,láti wá àti láti ṣàwárí ọgbọ́nàti ìdí ohun gbogbo, àti láti mọ àgọ́ ìwàbúburú àti ti ìsínwín tàbí òmùgọ̀.
26. Mo rí ohun tí ó korò ju ikú lọobìnrin tí ó jẹ́ ẹ̀bìtì,tí ọkàn rẹ̀ jẹ́ tàkútétí ọwọ́ rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀wọ̀n,ọkùnrin tí ó bá tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn yóò le è yọ sílẹ̀ṣùgbọ́n ẹlẹ́ṣẹ̀ kò le è bọ́ nínú tàkúté rẹ̀.