Oníwàásù 6:9-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ohun tí ojú rí sànju ìfẹnúwákiri lọAṣán ni eléyìí pẹ̀lúó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.

10. Ohunkóhun tí ó bá ti wà ti ní orúkọ,ohun tí ènìyàn jẹ́ sì ti di mímọ̀;kò sí ènìyàn tí ó le è ja ìjàkadìpẹ̀lú ẹni tí ó lágbára jùú lọ

11. Ọ̀rọ̀ púpọ̀,kì í ní ìtumọ̀èrè wo ni ènìyàn ń rí nínú rẹ̀?

12. Àbí, ta ni ó mọ ohun tí ó dára fún ènìyàn ní ayé fún ọjọ́ ayé kúkúrú àti aṣán tí ó ń là kọjá gẹ́gẹ́ bí òjìji? Ta ni ó le è sọ fún mi, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn lẹ́yìn tí ó bá lọ tán? kò sí!

Oníwàásù 6