4. Ó wà láìní ìtumọ̀, ó lọ nínú òkùnkùn, nínú òkùnkùn sì ni orúkọ rẹ̀ farapamọ́ sí.
5. Bí ó ti jẹ́ wí pé kò rí oòrùn tàbí mọ ohunkóhun, ó ní ọ̀pọ̀ ìṣinmi ju ti okùnrin náà lọ.
6. Kó dà, bí ó wà láàyè fún ẹgbẹ̀rún ọdún méjì yípo ṣùgbọ́n tí ó kùnà láti gbádùn ohun-ìní rẹ̀. Kìí ṣe ibìkan ni gbogbo wọn ń lọ?
7. Gbogbo wàhálà tí ènìyàn ń ṣe nítorí àtijẹ niṣíbẹ̀ ikùn rẹ̀ kò yó rí
8. Kí ni àǹfàní tí ọlọgbọ́n ènìyàn nílórí aṣiwèrè?Kí ni èrè talákà ènìyànnípa mímọ bí yóò ṣe hùwà níwájú àwọn tó kù?