1. Ṣọ́ ìrìn rẹ nígbà tí o bá lọ sí ilé Ọlọ́run. Kí ìwọ kí ó sì múra láti gbọ́ ju àti se ìrúbọ aṣiwèrè, tí kò mọ̀ wí pé òun ń ṣe búburú.
2. Má ṣe yára pẹ̀lú ẹnu un rẹmá sọ ohunkóhun níwájú Ọlọ́runỌlọ́run ń bẹ ní ọ̀runÌwọ sì wà ní ayé,nítorí náà jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ mọ ní ìwọ̀n
3. Gẹ́gẹ́ bí àlá tí ń wá, nígbà tí ìtọ́jú púpọ̀ wàbẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ nígbà tí ọ̀rọ̀ bá pọ̀jù.
4. Nígbà tí ó bá ṣe ìlérí sí Ọlọ́run, má ṣe pé ní mímú ṣẹ kò ní inú dídùn sí òmùgọ̀, mú ìlérí rẹ sẹ.