Oníwàásù 4:7-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Lẹ́ẹ̀kan síi mo tún rí ohun asán kan lábẹ́ oòrùn:

8. Ọkùnrin kan dá wà,kò ní ọmọkùnrin kankan tàbí ẹbíwàhálà rẹ̀ kò lópin,ṣíbẹ̀, ọ̀rọ̀ ohun ìní rẹ̀ kò tẹ́ ẹ lọ́rùn, ó bèèrè pé,“Nítorí ta ni mo ṣe ń ṣe wàhálà”“àti wí pé kí ni ìdí tí mo fi ń fi ìgbádùn du ara mi?”Eléyìí náà aṣán niiṣẹ́ ìbànújẹ́ ni.

9. Ẹni méjì ṣàn ju ẹnìkan,nítorí wọ́n ní ààbò rere fún iṣẹ́ wọn:

10. Tí ọ̀kan bá ṣubú lulẹ̀,ọ̀rẹ́ rẹ̀ le è ràn án lọ́wọ́ kí ó fàá sókè,ṣùgbọ́n ìyọnu ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣubútí kò sì ní ẹni tí ó le è ràn-án lọ́wọ́!

11. Àti pẹ̀lú pé, bí ẹni méjì bá ṣùn pọ̀, wọn yóò móoru.Ṣùgbọ́n báwo ni ẹnìkan ṣe le è dá nìkan móoru?

12. Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé, a le è kojú ogun ẹnìkan,àwọn méjì le è gbìjà ara wọn,ìkọ́ okùn mẹ́ta kì í dùn-ún yàra fà já

13. Òtòsì ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ tí ó ṣe ọlọ́gbọ́n, ó ṣàn ju arúgbó àti aṣiwèrè ọba lọ tí kò mọ bí yóò ti ṣe gba ìmọ̀ràn,

14. Nítorí pé láti inú túbú ni ó ti jáde ìjọba, bí a tilẹ̀ bí i ní talákà ní ìjọba rẹ̀.

15. Mo rí gbogbo alààyè tí ń rìn lábẹ́ oòrùn, pẹ̀lú ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ kejì tí yóò gba ipò ọba yìí.

16. Gbogbo àwọn tí ó wà ní wájú wọn kò sì lópin, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn ní ó jọba lé lórí, ẹni tí ó wà ní ipò yìí kò dùn mọ́ àwọn tí ó tẹ̀lé wọn nínú. Aṣán ni eléyìí pẹ̀lú jẹ́, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni.

Oníwàásù 4