Oníwàásù 4:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Mo sì tún wò ó, mo sì ri gbogbo ìnilára tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn:mo rí ẹkún àwọn tí ara ń ni, wọn kòsì ní Olùtùnú kankan,agbára wà ní ìkápá àwọn tí ó ń ni wọ́n lárawọn kò sì ní olùtùnú kankan.

2. Mo jowú àwọn tí wọ́n ti kútí wọ́n sì ti lọ,ó ṣàn fún wọn ju àwọntí wọ́n sì wà láàyè lọ.

3. Nítòótọ́, ẹni tí kò tí ì sí sàn juàwọn méjèèjì lọ:ẹni tí kò tí ì rí iṣẹ́ búburútí ó ń lọ ní abẹ́ oòrun.

Oníwàásù 4