Oníwàásù 3:5-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ìgbà láti tú òkúta ká àti ìgbà láti ṣà wọ́n jọìgbà láti ṣún mọ́ àti ìgbà láti fà ṣẹ́yìn

6. Ìgbà láti wá kiri àti ìgbà láti ṣàì wá kiriìgbà láti pamọ́ àti ìgbà láti jù nù,

7. Ìgbà láti ya àti ìgbà láti ránìgbà láti dákẹ́ àti ìgbà láti ṣọ̀rọ̀

8. Ìgbà láti níìfẹ́ àti ìgbà láti kóríraìgbà fún ogun àti ìgbà fún àlàáfíà.

9. Kí ni òṣìṣẹ́ jẹ ní èrè nínú wàhálà rẹ̀?

10. Mo ti rí àjàgà tí Ọlọ́run gbé lé ọmọ ènìyàn.

Oníwàásù 3