2. Ìgbà láti bí àti ìgbà kíkú,ìgbà láti gbìn àti ìgbà láti fàtu.
3. Ìgbà láti pa àti ìgbà láti mú lára dáìgbà láti wó lulẹ̀ àti ìgbà láti kọ́.
4. Ìgbà láti ṣunkún àti ìgbà láti rín ẹ̀rínìgbà láti sọ̀fọ̀ àti ìgbà láti jó
5. Ìgbà láti tú òkúta ká àti ìgbà láti ṣà wọ́n jọìgbà láti ṣún mọ́ àti ìgbà láti fà ṣẹ́yìn
6. Ìgbà láti wá kiri àti ìgbà láti ṣàì wá kiriìgbà láti pamọ́ àti ìgbà láti jù nù,
7. Ìgbà láti ya àti ìgbà láti ránìgbà láti dákẹ́ àti ìgbà láti ṣọ̀rọ̀
8. Ìgbà láti níìfẹ́ àti ìgbà láti kóríraìgbà fún ogun àti ìgbà fún àlàáfíà.
9. Kí ni òṣìṣẹ́ jẹ ní èrè nínú wàhálà rẹ̀?
10. Mo ti rí àjàgà tí Ọlọ́run gbé lé ọmọ ènìyàn.
11. Ó ti ṣe ohun gbogbo dáradára ní àsìkò tirẹ̀, ó sì ti fi èrò nípa ayérayé sí ọkàn ọmọ ènìyàn, ṣíbẹ̀, wọn kò le ṣe àwárí ìdí ohun tí Ọlọ́run ti ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin.
12. Mo mọ̀ wí pé kò sí ohun tí ó dára fún ènìyàn ju pé kí inú wọn dùn kí wọn sì ṣe rere níwọ̀n ìgbà tí wọ́n sì wà láàyè.
13. Wí pé: kí olúkúlùkù le è jẹ, kí wọn sì mu, kí wọn sì rí ìtẹ́lọ́rùn nínú gbogbo iṣẹ́ wọn ẹ̀bùn Ọlọ́run ni èyí jẹ́.
14. Mo mọ̀ wí pé ohun gbogbo tí Ọlọ́run ṣe ni yóò wà títí láé, kò sí ohun tí a lè fi kún un tàbí kí a yọ kúrò nínú rẹ̀. Ọlọ́run ṣe èyí kí ènìyàn le è ní ìbẹ̀rù rẹ̀ ni.