Oníwàásù 1:3-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Kí ni ènìyàn rí jẹ ní èrè lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀lórí èyí tí ó ń ṣe wàhálà sí lábẹ́ oòrùn?

4. Bí ìran kan ti wá ni ìran mìíràn ń kọjá lọ,síbẹ̀ ayé dúró títí láé.

5. Oòrùn ń ràn, oòrùn sì ń wọ̀,ó sì sáré padà síbi tí ó tí yọ.

6. Afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ sí ihá gúṣù,Ó sì ń fẹ́ yípo sí ìhà àríwá,a sì tún padà sí ọ̀nà rẹ̀.

7. Gbogbo odò ń sàn sí inú òkunsíbẹ̀síbẹ̀ òkun kò kún.níbi tí àwọn odò ti wá,níbẹ̀ ni wọ́n tún padà sí

8. Ohun gbogbo ni ó ń mú àárẹ̀ wá,ju èyí tí ẹnu le è ṣọojú kò tí ì rí ìrírí tí ó tẹ́ẹ lọ́rùn,bẹ́ẹ̀ ni, etí kò tí ì kún fún gbígbọ́.

9. Ohun tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ náà ni yóò sì máa wà, ohun tí a ti ṣe sẹ́yìnòun ni a ó tún máa ṣe padàkò sí ohun tuntun lábẹ́ oòrùn.

Oníwàásù 1