Oníwàásù 1:3-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Kí ni ènìyàn rí jẹ ní èrè lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀lórí èyí tí ó ń ṣe wàhálà sí lábẹ́ oòrùn?

4. Bí ìran kan ti wá ni ìran mìíràn ń kọjá lọ,síbẹ̀ ayé dúró títí láé.

5. Oòrùn ń ràn, oòrùn sì ń wọ̀,ó sì sáré padà síbi tí ó tí yọ.

6. Afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ sí ihá gúṣù,Ó sì ń fẹ́ yípo sí ìhà àríwá,a sì tún padà sí ọ̀nà rẹ̀.

7. Gbogbo odò ń sàn sí inú òkunsíbẹ̀síbẹ̀ òkun kò kún.níbi tí àwọn odò ti wá,níbẹ̀ ni wọ́n tún padà sí

Oníwàásù 1