Onídájọ́ 9:36-46 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

36. Nígbà tí Gáálì rí àwọn ènìyàn náà, ó sọ fún Ṣébúlù pé, “Wòó, àwọn ọkùnrin kan ń bọ̀ wá, láti orí àwọn òkè!”Ṣébúlù dá a lóhùn pé, “àṣìṣe lò ǹ ṣe oò ríi dáadáa, òjìji òkè ni ò ń pè ní àwọn ènìyàn.”

37. Gáálì ké ó ní, “Wòkè, àwọn ènìyàn ń tọ̀ wá bọ̀ láti agbede-méjì ilẹ̀ wá àti ẹ̀gbẹ́ kan n sì ń bọ̀ láti ìhà igi àwọn aláfọ̀ṣẹ tí ń jẹ́ óákù-Méónénímù.”

38. Nígbà náà ni Ṣébúlù dá a lóhùn pé, “Níbo ni ẹnu tí ó ń ṣe ni wà báyìí. Ṣe bí o wí pé, ‘Ta ni Ábímélékì tí àwa ó fi máa sìn ín?’ Àwọn ẹni tí ó gàn án kọ́ nìyí? Jáde lọ kí o sì bá wọn jà!”

39. Gáálì sì ṣíwájú àwọn ogun ará Ṣékémù lọ kọjú Ábímélékì láti bá wọn jagun.

40. Ábímélékì sì lé e, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ogun ṣubú wọ́n sì gbọgbẹ́ bí wọ́n ṣe ń sáá lọ, títí dé ẹnu ọ̀nà ibùdó ìlú náà.

41. Ábímélékì dúró sí Árúmà, nígbà tí Ṣébúlù lé Gáálì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ kúrò ni Ṣékémù, kò sì jẹ́ kí wọ́n gbé Ṣékémù mọ́.

42. Ní ọjọ́ kejì àwọn ará Ṣékémù sì jà lọ́ sí oko, ẹnìkan ló ṣe òfófó rẹ̀ fún Ábímélékì.

43. Ó kó àwọn ènìyàn rẹ̀, ó pín wọn sí ẹgbẹ́ mẹ́ta ó sì sá pamọ́ sí inú oko. Nígbà tí ó sì rí tí àwọn ènìyàn náà ń jáde kúrò nínú ìlú, ó dìde ó gbógun tì wọ́n.

44. Ábímélékì àti àwọn ọmọ ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sáré síwájú, wọ́n gba ẹnu ibodè ìlú náà, wọ́n sì dúró níbẹ̀. Àwọn ẹgbẹ́ méjì tókù sì sáré sí àwọn tó wà ní oko wọ́n sì gbógun tì wọ́n.

45. Ní gbogbo ọjọ́ náà ni Ábímélékì fi bá àwọn ará ìlú náà jà, ó sì ṣẹ́gun wọn, ó sì pa àwọn ènìyàn ìlú náà ó wó ìlú náà palẹ̀ pátapáta ó sì fọ́n iyọ̀ sí i.

46. Àwọn ènìyàn ilé ìṣọ́ Ṣékémù gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n sá lọ fún ààbò sí inú ilé ìsọ́ agbára Ọlọ́run Bérítì (El-Bérítì).

Onídájọ́ 9