Onídájọ́ 8:10-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ní àsìkò náà Ṣébà àti Ṣálímúnà wà ní Kákórì pẹ̀lú ọmọogun wọn tí ó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dógún (15,000) ọkùnrin, àwọn wọ̀nyí ni ó ṣẹ́ kù nínú gbogbo ogun àwọn ènìyàn apá ìlà oòrùn, nítorí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́fà ọkùnrin tí ó fi idà jà ti kú ní ojú ogun.

11. Gídíónì gba ọ̀nà tí àwọn dáràndáràn máa ń rìn ní apá ìhà ìlà oòrùn Nóbà àti Jógíbíà ó sì kọjú ogun sí àwọn ọmọ ogun náà nítorí wọ́n ti túra sílẹ̀.

12. Ṣébà àti Ṣálímúnà, àwọn ọba Mídíánì méjèèjì sá, ṣùgbọ́n Gídíónì lépa wọn ó sì mú wọn, ó run gbogbo ogun wọn.

13. Gídíónì ọmọ Jóásì gba ọ̀nà ìgòkè Hérésì padà sẹ́yìn láti ojú ogun.

14. Ó mú ọ̀dọ́mọkùnrin kan ará Ṣúkótì, ó sì béèrè àwọn ìbéèrè ní ọwọ́ rẹ̀, ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì kọ orúkọ àwọn ìjòyè Ṣúkótì mẹ́tadínlọ́gọ́rin (77) fún un tí wọ́n jẹ́ àgbààgbà ìlú náà.

15. Nígbà náà ni Gídíónì wá ó sọ fún àwọn ọkùnrin Ṣúkótì pé, “Ṣébà àti Sálímúnà nìwọ̀nyí nípa àwọn tí ẹ̀yin fi mí ṣẹ̀fẹ̀ nígbà tí ẹ wí pé, ‘Ṣé ó ti ṣẹ́gun Ṣébà àti Ṣálímúnà? Èéṣe tí àwa ó fi fún àwọn ọmọ ogun rẹ tí ó ti rẹ̀ ní oúnjẹ?’ ”

16. Ó mú àwọn àgbààgbà ìlú náà, ó sì fi kọ́ àwọn Ṣúkótì lọ́gbọ́n nípa jíjẹ wọ́n níyà pẹ̀lú àwọn ẹ̀gún aṣálẹ̀ àti ẹ̀gún ọ̀gàn.

17. Ó wọ ilé ìṣọ́ Péníélì, ó sì pa àwọn ọkùnrin ìlú náà.

18. Gídíónì bi Ṣébà àti Ṣálímúnà pé, “Irú ọkùnrin tí ẹ pa ní Tábórì, bá wo ni wọ́n ṣe rí?”“Àwọn ọkùnrin náà dàbí rẹ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dàbí ọmọ ọba,” ní ìdáhùn wọn.

19. Gídíónì dáhùn pé, “Arákùnrin mi ni wọ́n, àwọn ọmọ ìyá mi. Mo fi Olúwa búra, bí ó bá ṣe pé ẹ dá ẹ̀mí wọn sí, èmi náà ò ní pa yín.”

20. Ó yí padà sí Jétérì, ọmọ rẹ̀ tí ó dàgbà jùlọ, ó wí fún un pé, “Pa wọ́n!” Ṣùgbọ́n Jétérì kò fa idà rẹ̀ yọ láti pa wọ́n nítorí ó jẹ́ ọ̀dọ́mọdé ẹ̀rù sì bà á láti pa wọ́n.

21. Ṣébà àti Ṣálímúnà dá Gídíónì lóhùn pé, “Wá pa wá fún raàrẹ, ‘Nítorí bí ènìyàn bá ti rí bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ yóò rí.’ ” Gídíónì bọ́ ṣíwájú ó sì pa wọ́n, ó sì mú ohun ọ̀sọ́ tí ó wà ní ọrùn àwọn ràkúnmí wọn.

22. Àwọn ará Ísírẹ́lì wí fún Gídíónì pé, “Jọba lórí wa—ìwọ, àwọn ọmọ rẹ àti àwọn ọmọ-ọmọ rẹ pẹ̀lú, nítorí tí ìwọ ti gbà wá lọ́wọ́ àwọn ará Mídíánì.”

Onídájọ́ 8