Onídájọ́ 5:18-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Àwọn ènìyàn Ṣébúlúnì fi ẹ̀mí wọn wéwu ikú;bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ènìyàn Náfítalì ní ibi gíga pápá.

19. “Àwọn ọba wá, wọ́n sì jà;àwọn ọba Kénánì jàní Tánákì ní etí odo Mégídò,ṣùgbọ́n wọn kò sì gba èrè owó.

20. Àwọn ìràwọ̀ já láti ojú ọ̀run wáláti ibùjókòó wọn ni wọ́n ti bá Ṣísérà jà.

Onídájọ́ 5